Foundation on the Rock

Nípa Wa

Nípa lílo ẹ̀kọ́ Kristi gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀, a ń fojú inú rí ìyípadà ìgbésí-ayé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, ìránṣẹ́, àti agbára Ẹ̀mí Mímọ́.

Pàdé Olùdásílẹ̀ Wa

Olùṣọ́-Àgùntàn Àgbà, Wòlíì àti Ajíhìnrere

Adelowo Olusoa Adediran

Pastọ̀ Olúṣọ́lá Adélọ́wọ́ Adédíran ni a bí sí ìlú Ọ̀yọ́, láti inú ẹbí Ọ̀jọ́yàgè. Ìgbésí-ayé rẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, àánú Rẹ̀ àti agbára Rẹ̀ tí ń yi ìgbésí-ayé ènìyàn padà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbé-ayé ìkókó rẹ̀ kún fún ìṣòro, tí ẹ̀kọ́ ilé-ìwé rẹ̀ sì kéré, ìbùkún àti ìtẹ́lọ́run Ọlọ́run ti ń tẹ̀lé ìrìn-àjò ayé rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀.

Ìgbésí-ayé Ìbẹ̀rẹ̀

Ní ọdún ìkókó ìgbésí-ayé rẹ̀, Pastọ̀ Olúṣọ́lá máa ń ṣàpèjúwe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó le, aláìgbọ́ràn, tí ó sì sábà máa ń kó ara rẹ̀ sínú ìwà ìdarudapọ̀. Lẹ́yìn tí ó parí ilé-ẹ̀kọ́ alakọbẹrẹ ní ìjọba ìbílẹ̀ Ojà Kọ́sọ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí kọńdọ́ọ̀kítà

Our Ìṣẹ́-Ọ̀nà

Our Ìṣẹ́-Ọ̀nà

Láti tọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu Kristi tí ó kún fún ìtara dágba, tí yóò yi àwọn àgbègbè wọn padà nípasẹ̀ agbára Ihinrere, tí yóò sì fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn nípasẹ̀ ìjosìn, ìkọ́ni ọmọ-ẹ́yìn, àti ìránṣẹ́.

Láti tọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Jesu Kristi tí ó kún fún ìtara dágba, tí yóò yi àwọn àgbègbè wọn padà nípasẹ̀ agbára Ihinrere, tí yóò sì fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn nípasẹ̀ ìjosìn, ìkọ́ni ọmọ-ẹ́yìn, àti ìránṣẹ́.

Ìran Wa

Ìran Wa

Láti jẹ́ ìjọ ọ̀pọ̀-ìran tí ń nípa lórí ìlú wa àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí ń dá ogún ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́ sílẹ̀, tí ń yi ìgbésí-ayé padà, tí ó sì ń kọ ìjọba Ọlọ́run sílẹ̀ lórí ayé.

Láti jẹ́ ìjọ ọ̀pọ̀-ìran tí ń nípa lórí ìlú wa àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, tí ń dá ogún ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́ sílẹ̀, tí ń yi ìgbésí-ayé padà, tí ó sì ń kọ ìjọba Ọlọ́run sílẹ̀ lórí ayé.

Ohun Tí A Gbà Gbọ́

Gbólóhùn ìgbàgbọ́ wa

A gbagbọ pe Jesu Kristi ni "ọna, otitọ ati iye." (Johannu 14:6)

A gbagbọ́ pé "kò sí ìgbàlà nínú ẹlòmíràn, nítorí kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run tí a fi fún ènìyàn, èyí tí a gbọ́dọ̀ fi gbà wá là." (Ìṣe àwọn Aposteli 4:12)

A gbagbọ pe "Bí a bá sọ pé a kò ní ẹ̀ṣẹ̀, àwa ń tàn ara wa jẹ, òtítọ́ kò sì sí nínú wa." (1 Johannu 1: 8)

Ọrọ naa lori oludasilẹ ijọ yii ni so ki

Mojẹ ọmọ bibi ilu Ọyọ Ni ago  agbo ile OJoyage. Olusoagutan Olusola Adelowo je enikan ti o ri oju rere Olorun gba pupo. Ni ibẹrẹ igbesi aye mi Mo jẹ ẹnikan ti o jẹ alagidi pupọ, jagunjagun, pẹlu aiṣedeede iwa. Modupẹ lọwọ olorun pe  unko wọ Ẹgbẹ Ajẹ tabi Ẹgbẹ Ole tabi ẹgbẹ okunkun Kankan. Sungbọn mojẹ ẹniken ti ko letosi ohun ti Jesu Kristi  fi mi pe rara. Ni ti ile-iwe, ko si oore-ọfẹ fun mi lati lọ si ile-iwe ti o dara ati kọja kilasi karun.

 

Lati igba ti mo ti kuro ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni oko kan ti ape ni oja koso mo bẹrẹ si ni se ọmọ ẹyin ọkọ kakiri kin to pade okunrin kan ti a pe orukorẹ ni “Asani ; ẹni to o ko mi bi ati sema mu igbo. Ti osi bẹrẹ si ma fun mi ni orisirisi ogun ti o ni agbara. Awan ikan wonyi ni ko jẹki ọrọ aye mi ti lẹ ni oju rara. Ka ma fa ọrọgun, momon.” motor (ọkọ) wa. Ti baba mi si gba iwe ẹri iwakọ fun mi. Lẹyin naa ni mo lọ si ilu Abuja lati lowa ọkọ fun at jenu.

 

Laie fa ọrọ gun, mo pa da wa sile ni ilu Ọyọ ni ọdun 2002 ti mo situn wa wo ise arobo/Trader. Ni gba ti mo pari  Lẹyin ọdun kan,  mo pada si ilu Abuja ni ọdun 2003. Lati wa owo isẹ lọ. Lẹ nu rẹẹn ni mo bẹẹrẹ situn wa motor ti mo fi pade pastor  ti oruko re je Gbeunga Ọdẹtola ti mo bẹẹrẹ si sun mon won.

 

Ẹni yi ni kan ni mo gbo lati ẹnu re pe mo ni ipe olusọ aguntan, Sugbon ko ye mi. Sugbon ọjọ  kan ti emi ko le gbagbe ni ọjọ ti mo gbọ ohun  Oluwa Olorun si eti mi 3-3- 2004 ti iderun si ba mi  so ọrọ gẹgẹ bi baba si ọmọ. Ẹru ba mi gidi gidi.  Lati ọjọ yi ni gbogbo ọnan ti mo ba dawọsi ti bẹrẹ si jasi pabo. Eyi lo mumi lati joko si ori oke fun osu meta ati ọjọ die  kin to pada si ile lati  lo bẹrẹ isẹ oluwa ninu ijọ kan ni ilu Ọyọ ti a pe oruko re ni Christ Power Evangelist Church. Leyin odun diẹ Ọlọrun tun mumi tẹsiwaju losi ijo miran ti a pe ni GRACE & GLORY BIBLE CHURCH ni ilu Ọyọ.  Ti mo si tun lo awon akoko kan ni bẹ. Lẹyin nan Ọlọrun mun mi lo silu EKo  ti mosi tun sisẹ ninu awon ijọ miran.  Ki Olorun to pasẹ fun mi  lati da ijọ tiwa na silẹ ni ọjọ kẹta, osu karun ọdun 2006. (03-05-2006)